Breaking News: Unilorin Alumi Association: 'We were warned' - Opinion
Breaking News: Breaking: Court Restrains Oyo Assembly from Further Impeachment Process Against Makinde’s Deputy, Olaniyan
Breaking News: Labour leaders physically assault Ogun journalists for covering strike, harass hospital workers
Breaking News: Congratulations Asiwaju – Osinbajo’s spokesperson accepts defeat
Breaking News: Finalissima: Messi steals show, beats European Champion, Italy
Emir Ìpínlẹ̀ Kánò, Àlàáji Àmínù Adó Báyéró lọ́jọ́ Ajé sọ fún obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn aya Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, arábìnrin Olúrẹ̀mí Tinúubú nígbà tí ó wá ṣe àbẹ̀wò sí ní ààfin rẹ̀ kí ó bá Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinúubú sọ̀rọ̀ lórí ìpèníjà tó ń bá àwon omo ilé yi fínra.
Nígbà tí ó ń gba aya orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lálejò, ó ní, “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní ọ̀nà oríṣiríṣi láti fi èròńgbà wa hàn àmọ́ ti aya Ààrẹ yóò tètè dé ọ̀dọ̀ Ààrẹ ju ọ̀nà yòókù lọ."
Èdè Haúsá ni ó fi sọ ọrọ yìí àmọ́ ọ̀kan lára àwọn agbèfọ́bà ló ṣe ògbifọ̀ rẹ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Ó sọ pé, “Mo gbà pé àjogúnbá ni wàhálà ilẹ̀ yìí àmọ́ èyí tó burú jáì ni ti ìgbé ayé tí kò fara rọ lásìkò ìjọba tó wà lóde báyìí èyí tí ó ń fẹ́ ọ̀nà àbáyọ ní kíákíá”.
Bákan náà, Emir tún mẹ́nubà èròńgbà láti gbé àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ ìjọba kan kúrò ní olú-ìlú ilẹ̀ wa ní Àbújá lọ sí Ìpínlẹ̀ Ààrẹ.
Àmínù Adó Báyéró sọ pé, ara ń fu òun bí Ààrẹ ṣe ń gbèrò láti gbé ẹ̀ka kan tó jẹ́ gbòógì ní ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ àti àjọ tó ń ṣàkóso ọkọ̀ ofurufu lọ sí ìpínlẹ̀ Èkó.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Emir ti ìlú Kánò sọ pé, "òun ti ń gba oríṣiríṣi àtẹ̀jíṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tó ń jà rànyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aráàlú tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wọn sì ń kọminú ìgbésẹ̀ Ààrẹ yìí.
Ó gba ìjọba àpapọ̀ lámọ̀ràn láti má ṣe figbá-kan-bọ̀kan nínú fún ọmọ Nàìjíríà lórí ọ̀rọ̀ yìí kí wọ́n sì bá wọn sọ èdè tí wọ́n gbọ́”.
Bákan náà, Báyéró rọ Ààrẹ láti túbọ̀ máa la àwọn aráàlú lọ́yẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní, “òun gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan kò lè sọ èròńgbà ìjọba pàtó, ó yẹ kí ó làá hàn gbogbo ọmọ Nàìjíríà èrèdí tí wọn ṣe ń fẹ́ dá àwọn ẹ̀ka ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ àti ti ọkọ ofurufu padà sí ìpínlẹ̀ Èkó.
"Ètò ààbò tó mẹ́hẹ náà jẹ́ ìpèníjà àti wàhálà tó ń bá àwọn èèyàn wọ̀yá ìjà, mo sì mọ̀ pé ìjọba tó wà lóde báyìí náà bá a bẹ́ẹ̀ ni àmọ́ a gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ akin kí ìpèníjà yìí lè rodò lọ mumi”.
Ó lu aya Ààrẹ lọ́gọ ẹnu bí ó ṣe ń jí gìrì sí itọju àwọn ọmọdé.
Ó gbà á lámọ̀ràn láti jẹ́ kí ètò tó ń ṣe agbátẹrù rẹ̀ lábẹ́ Ètò Ìrètí Ìsọdọ̀tun má ṣe gbàgbé àwọn tó kù díẹ̀ káàtò fún.
Lori ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọbìnrin, Báyéró sọ fún un pé kí ó fojú lámèyítọ́ wò ó kí ó lè wá nǹkan ṣe sí i.
Ọba náà gbóríyin fún Olúrẹ̀mí Tinúubú bí ó ṣe ṣe adúrótì fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Plateau lásìkò gbódó-n-róṣọ tó wáyé níbẹ̀, ó wá ṣe é ládúrà pé kí yóò túbọ̀ lè ṣe irú rẹ̀ fún àwọn aláìní yòókù.
Newsletter
We are not gonna make spamming
Copyright By @ HorizonTimes - 2025
BACK TO TOP