Breaking News: Unilorin Alumi Association: 'We were warned' - Opinion
Breaking News: Breaking: Court Restrains Oyo Assembly from Further Impeachment Process Against Makinde’s Deputy, Olaniyan
Breaking News: Labour leaders physically assault Ogun journalists for covering strike, harass hospital workers
Breaking News: Congratulations Asiwaju – Osinbajo’s spokesperson accepts defeat
Breaking News: Finalissima: Messi steals show, beats European Champion, Italy
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn lọ́jọ́ Ọjọ́rú, ti kéde owó tí ó tó bílíọ̀nù márùn-ún náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìránwọ́ láti kojú wàhálà tó ń kojú ètò ọ̀rọ̀ ajé ní gbogbo ẹ̀ka.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọmọọba Dàpọ̀ Abíọ́dún sọ èyí nígbà tí ó bá ń àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ọ́fíìsì rẹ̀ tó wà ní Òkè-Mọsàn ní Abẹ́òkúta.
Abíọ́dún sọ onírúurú ọ̀nà tí ìjọba ti là kalẹ̀ láti mú ìdínkù bá ìpayínkeke tí ó ń bá àwọn èèyàn fínra.
Gómìnà tún ṣàfikún rẹ̀ pé, owó ìránwọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, owó madáńdófò lórí ètò ìlera, sísan owó àjẹsílẹ̀ owó tí wọn ń yọ lórí owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú pípín oúnjẹ fún àwọn aráàlú wà lára ìgbésẹ̀ ìjọba.
Ó sọ pé, “Àwọn kò kọ etí ikún sí bí àwọn aráàlú ṣe ń kígbe lórí bí owó ọjà ṣe ń gbówó lórí gegere àti bí owó náírà ṣe ń já wálẹ̀, ó sọ pé gbogbo ọ̀nà ni àwọn ń wá láti lè mú ìnira yìí kúrò kí ìgbàyé gbádùn gbogbo mùtúmùwà lè túbọ̀ rú gọ́gọ́ sí.
Ó ní, àfojúsùn àwọn ni láti gbé ìgbésẹ̀ tí yóò mú ìnira tí àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí ń kojú dínkù jọjọ.
“Ní ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́, a óò kọ́kọ́ ṣètò ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìránwọ́ fún àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́wàá akẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo tìbútòró àwọn ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Nígbà tí ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ yìí tí ó fẹ́rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tadínlọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹgbẹ̀ta tó kù díẹ̀ káàtò fún ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásítì jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní owó ìránwọ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà.
Ní ẹ̀ka ètò ìlera, ó sọ di mímọ̀ pé, "a ó pèsè owó adíyelófò fún àwọn aláboyún, ọmọdé, àgbàlagbà, ìyàlọ́jà àti àwọn oníṣe ọwọ́ tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.
"A ó tún pèsè oúnjẹ bí i ìrẹsì àti oúnjẹ mìíràn fún àwọn èèyàn tí ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún jákèjádò ìpínlẹ̀ Ògùn."
Ní ti àwọn òṣìṣẹ́, ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ sísán owó àjẹsílẹ̀ tí ìjọba àná jẹ wọ́n. "Fún ìdí èyí, ní báyìí, a ó máa san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù náírà lóṣooṣù.
"Gẹ́gẹ́ bí ìjọba tó mọ ohun tó ń ṣe, tó sì tún fi aráàlú sọ́kàn, èyí ló mú kí àpapọ̀ owó tí à ń fẹ́ san báyìí jẹ́ bílíọ̀nù márùn-ún náírà ní gbogbo ẹ̀ka ètò ọ̀rọ̀ ajé ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.
“Ojúṣe ìjọba ni láti pèsè ààbò tó dúró o re fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn aráàlú, Abíọ́dún sọ bẹ́ẹ̀”.
Newsletter
We are not gonna make spamming
Copyright By @ HorizonTimes - 2024
BACK TO TOP